Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profileg
Yoruba Proverbs

@yoruba_proverbs

Seeks to propagate Yoruba proverbs and increase their usage thereby preserving the Yoruba language and the wisdom of the Yoruba people for posterity.

ID:395286435

linkhttps://www.amazon.com/stores/Ayotunde-O.-Joshua/author/B01N4ON1PM?ref=ap_rdr&isDramIntegrated=true& calendar_today21-10-2011 12:44:51

12,5K Tweets

252,3K Followers

584 Following

Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Bí èyàn bá ní ogún èèyàn kò lè mú òun, kó léèwọ̀ bí a ba fi ogójì dán an wò. /
If someone brags that 20 people cannot apprehend him, it is not out of place, if 40 people are tried on him.

[Don't brag; modesty is a virtue.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

A kì í bá ara ẹni tan kí á fa ara ẹni n'ítan ya. /
To be related to someone is no reason to be unconscionably dependent on him or her.

[Do not abuse your privilege; good to set and operate within healthy boundaries; there is a limit to everything.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Ìgbín tó fi ọdún kan rin ìrìn àjò, ní alángbá ò lè rìn. /
The snail that took a year for its trip, derides the lizard as tardy.

[Don't meddle. Focus on your own affairs.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Ìmàdò ì bá ṣe bí ẹlẹ́dẹ̀ a bà'lú jẹ́; ẹrú ì bá jọba ará ìlú ì bá tí kù'kan. /
Were the warthog in place of a pig, it would ravage the town; were a slave made king, he would spare no one.

[Positions of responsibility call for comparative competency.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Òkè lọwọ́ afúnni ńgbé; ìsàlẹ̀ lọwọ́ ẹni tó ńgbà á ńwà.
The hand of a giver is always at the top; the hand of the receiver stays below.

[Giving elevates; generosity pays.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Bí ọkọ̀ kan ó re Ejìnrìn, ẹgbẹgbẹ̀rún ẹ̀ á lọ. /
If a bus won't go to Ejìnrìn town, thousands others will.

[Alternatives exist: be open-minded to consider them; there is always a way out: keep hope alive.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Orí ò mọ ibùsùn; ìbá tún ibẹ̀ ṣe láàárọ̀. /
No one knows his or her future for certain; else one would have prepared for it, ahead of time.

[We can only plan; no one knows the future for certain.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Eré tí ajá bá fi ogún ọdún sá, ìrin fàájì ni fún ẹṣin. /
A race that takes dogs twenty years is a mere leisurely walk to horses.

[Different strokes for different folks; what proves a challenge to one may well be a walkover to another.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Ọjọ́ tí orí bá ti kúrò lára ejò ló di okùn lásán. /
The day the head leaves the body is when the snake becomes a mere rope.

[Leadership is ever crucial: without the head, full potential can hardly be realised.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Ọjọ́ àjùbà làgbẹ̀ ńnáání àdá; ọjọ́ tí tọ́ọ́rọ́ bá bọ́ sínú ṣaágo là ńnáání ọmọ alápá tínrín. /
The farmer values the cutlass when the farm is to be ploughed: we value a child of thin arm when a coin falls into a jug.

[No one is useless: we all have our place.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Aláǹgbá tó jábọ́ lórí ìrókò, ó ní bí ẹnìkan ò yin òun, òun á yin ara òun. /
The lizard that fell from a teak tree unharmed, says if it is not hailed by anyone, it will hail itself.
[It is okay to be your own cheerleader; celebrate your successes.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Bí èbù ò rà, a kò lè fi ojú kan ègbodò. /
If the yam seedlings are not allowed to rot (when planted), no new yams can be harvested.

[Good things take time: be patient and persevere; some things may have to get worse before they get better.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Ẹni a ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí ìgbà tí ọlọ́ṣa ko ni lẹ́rù lọ ni. /
To be kind to a person who isn't thankful is akin to being robbed by a thief.
[Attitude of gratitude is it; be ever thankful.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Bí a bá ní ká dijú kí ẹni burúkú kọjá, a kò ní mọ ìgbà tí ẹni rere máa lọ. /
If we were to close our eyes so as not to see a wicked person passing by, we may well miss a good person as well.

[Be tolerant; be forward-looking; don't be vindictive.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Ọ̀bẹ kì í mú kó gbẹ́ èkù ara rẹ̀. /
A knife cannot be so sharp as to carve its handle.

[We need one another; no man is an island.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Èéfín ni ìwà; kò ṣeé fi pamọ́. /
Character is like smoke; it cannot be covered up.

[No hypocrisy; we cannot pretend to be what we are not for very long; ultimately, who we really are will show through.]

account_circle
Yoruba Proverbs(@yoruba_proverbs) 's Twitter Profile Photo

Kò sí òbúrẹ́wà kan ńbì kan; òṣì ló ńmú ẹwà á ṣì. /
There is no ugliness anywhere; deprivation is what messes up beauty.

[Lack can impose undue limitations: with access to the right resources and support, everyone can go far: despise no one.]

account_circle